Tuesday, 16 August 2016

THE TENENTS OF THE APOSTOLIC CHURCH

AKOSO IGBAGBO

1- Fifi enu ara re Jeri igbala re ninu Kristi.

2- Gbigba eto ati gbigboran si awon alakosso ijo lenu , Awon aposteli , awon Alagba ,awon diakoni okunrin ati obirin

3- Wiwa si gbogbo awon ipade ijo ati diduro ninu idapo kikun,eyini nipe ki o ma ju igba meta lo ti iwo ki yio wa si ibi idapo lai si idi pataki fun aiwa re na .

4- Gbigba awon eko pataki ti ijo pelu awon ilana meji na eyini Baptismu nipa ti iribomi ati onje ale oluwa.

5- Pe ki iwo se iranlowo fun itileyin Ona na gegebi ati ko ninu oro olorun .

6- Pe ki iwo pa imoran ati asiri ijo mo larin ijo.

7- Pe iwo ngbadura o si nse iranlowo fun olukuluku ero ijo ni iranti pe eya lapapo la je ninu ara Kristi.

8- Ki o si ma lakaka lati pa isokan Emi mo ni idapo alafia.

     AKOSO IWA HIHU

1- Mase wa si ile olorun ni aigbadura ki o to wa.

2- Tete de ibi ijoko re ki isin to bere , nipa be iwo yio je apere rere fun awon apelehin ati awon alafara.

3- Mu awon omo re wa si ile olorun pelu re, ati awon iyekan re ati awon iranse re ,awon na ni emi lati gbala bi tire , ise re si ni lati toju won .

4- Fi oluso-agutan tabi alabojuto ijo se ore korikosun , Iwo nfe ibakedun , iranlowo ati imoran re,Ma gbadura fun ni igbagbogbo .

5- Fi ile olorun se ibugbe emi re.

6- Nigbati o ba nsoro ninu ile lakoko faji,mase fi enu egan soro awon iranse olorun tabi ise iranse won loju awon omode, Bi o ba gbin afefe , si ma reti ati ka iji .

7- Mu BIBELI re lowo lo si ile olorun .

8- Wo inu ile olorun towotowo , fi igbona okan gbadura ,fi ipapo okan teti lele, fi okan imore yin I.ki o si sin olorun ninu ewa iwa mimo.
E lo si enu ona re ti eyin ti Ope ati si agbala re ti eyin ti iyin , ema dupe fun , ki esi ma fi ibukun fun oruko re.

      IDI IGI EKO IJO TI APOSTELI

1- Isokan eni meta ti nbe ninu okan na.

2- Pe eda enia buru jai oranyan si ni ironu piwada ati atunbi ati iparun ayeraye fun awon ti ko ronu piwada titi di ojo ikeyin .

3- Ibi wundia igbe aye ailese iku etutu ajinde isegun , igoke re orun , ibebe jesu Kristi oluwa sibe , bibo re lekeji ati ijoba re lori aye fun egberun Odun.

4- Idalare ati isoni di mimo onigbagbo nipa ise asepe ti Kristi ti se

5- Baptismu ti EMI-MIMO fun awon onigbagbo pelu awon ami ti ntele e.

6- Awon ebun mesan ti EMI-MIMO fun imuduro ,igbiyanju ati itunu ijo ti nse ara Kristi.

7- Majemu ti Baptismu nipa iribomi ati onje ale oluwa.

8- Nipa imisi ati ase Olorun ni afi ko iwe MIMO.

9- Akoso ijo nipa awon Aposteli ,Woli ajihinrere , Oluso-agutan ,olukoni alagba ati awon Diakoni .

10- O sese pe ki enia ki o subu kuro ni ore-ofe.

11- Dida idamewa ati ore aigbodo mase ni.

12- Iwosan lailo ogun nipa igboran si ase Oluwa wa Jesu Kristi ati igbagbo ninu oruko ati itoye eje re fun gbogbo aisan ,arun ati ailera.the

No comments:

Post a Comment